Isaiah 15

Àsọtẹ́lẹ̀ lòdì sí Moabu

1 aỌ̀rọ̀-ìmọ̀ tí ó kan Moabu:
A pa Ari run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
A pa Kiri run ní Moabu,
òru kan ní a pa á run!
2Diboni gòkè lọ sí tẹmpili rẹ̀,
sí àwọn ibi gíga rẹ̀ láti sọkún,
Moabu pohùnréré lórí Nebo àti Medeba.
Gbogbo orí ni a fá
gbogbo irùngbọ̀n ni a gé dànù.
3Wọ́n wọ aṣọ ọ̀fọ̀ ní ojú òpópónà,
ní àwọn òrùlé àti àwọn gbàgede ìlú.
Wọ́n pohùnréré
Wọ́n dọ̀bálẹ̀ pẹ̀lú ẹkún.
4Heṣboni àti Eleale ké sóde,
ohùn wọn ni a gbọ́ títí fi dé Jahasi.
Nítorí náà ni àwọn ọmọ-ogun Moabu ṣe kígbe
tí ọkàn wọn sì rẹ̀wẹ̀sì.

5Ọkàn mi kígbe sókè lórí Moabu;
àwọn ìsáǹsá rẹ sálà títí dé Soari,
títí fi dé Eglati-Ṣeliṣi.
Wọ́n gòkè lọ títí dé Luhiti
wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń lọ,
Ní òpópónà tí ó lọ sí Horonaimu
wọ́n ń pohùnréré ìparun wọn
6Gbogbo omi Nimrimu ni ó ti gbẹ
àwọn koríko sì ti gbẹ,
gbogbo ewéko ti tán
ewé tútù kankan kò sí mọ́.
7Báyìí gbogbo ọrọ̀ tí wọ́n ti ní
tí wọ́n sì tò jọ
wọ́n ti kó wọn kọjá lọ lórí i gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́
odò Poplari.
8Gbohùngbohùn ń gba igbe wọn dé
ìpẹ̀kun ilẹ̀ Moabu;
ìpohùnréré wọn lọ títí dé Eglaimu,
igbe ẹkún wọn ni a gbọ́ títí dé kànga Elimu.
9Omi Dimoni kún fún ẹ̀jẹ̀,
síbẹ̀ èmi ó tún mu ohun tí ó jù báyìí lọ wá sórí Dimoni—
kìnnìún kan wá sórí àwọn ìsáǹsá Moabu
àti lórí àwọn tí ó tún ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ náà.

Isaiah 16

1Fi ọ̀dọ́-àgùntàn ṣe ẹ̀bùn
ránṣẹ́ sí aláṣẹ ilẹ̀ náà,
láti Sela, kọjá ní aginjù,
lọ sí orí òkè ọ̀dọ́mọbìnrin Sioni.
2Gẹ́gẹ́ bí alárìnkiri ẹyẹ
tí a tì jáde kúrò nínú ìtẹ́,
bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni àwọn obìnrin Moabu
ní àwọn ìwọdò Arnoni.

3“Fún wa ní ìmọ̀ràn
ṣe ìpinnu fún wa.
Jẹ́ kí òjìji rẹ dàbí òru,
ní ọ̀sán gangan.
Fi àwọn ìsáǹsá pamọ́,
má ṣe fi àwọn aṣàtìpó han
4Jẹ́ kí àwọn ìsáǹsá Moabu gbé pẹ̀lú rẹ,
jẹ́ ààbò fún wọn kúrò lọ́wọ́ ìparun.”

Aninilára yóò wá sí òpin,
ìparun yóò dáwọ́ dúró;
òfinràn yóò pòórá kúrò lórí ilẹ̀.
5Nínú ìfẹ́ a ó fi ìdí ìjọba kan múlẹ̀,
ní òdodo ọkùnrin kan yóò jókòó lórí rẹ̀
ẹnìkan láti ilé Dafidi wá.
Ẹni yóò ṣe ìdájọ́, yóò sì máa wá ìdájọ́,
yóò sì máa yára wá ohun tí í ṣe òdodo.

6Àwa ti gbọ́ nípa ìgbéraga Moabu,
ìwọ̀sí ìgbéraga rẹ̀ àti fùlenge fùlenge,
gààrù rẹ̀ àti àfojúdi rẹ̀,
ṣùgbọ́n ìfọ́nnu rẹ̀ jẹ́ ìmúlẹ̀mófo.
7Nítorí náà ni àwọn ará Moabu hu,
wọ́n jùmọ̀ hu lórí Moabu.
Sọkún kí o sì banújẹ́
fún àkàrà díndín Kiri-Hareseti.
8Gbogbo pápá oko Heṣboni ti gbẹ,
bákan náà ni àjàrà Sibma rí.
Àwọn aláṣẹ àwọn orílẹ̀-èdè
wọ́n tẹ àwọn àyànfẹ́ àjàrà mọ́lẹ̀,
èyí tí ó ti fà dé Jaseri
ó sì ti tàn dé agbègbè aginjù.
Àwọn èhíhù rẹ̀ fọ́n jáde,
ó sì lọ títí ó fi dé Òkun.
9Nítorí náà mo sọkún, gẹ́gẹ́ bí Jaseri ṣe sọkún,
fún àwọn àjàrà Sibma.
Ìwọ Heṣboni, Ìwọ Eleale,
mo bomirin ọ́ pẹ̀lú omi ojú!
Igbe ayọ̀ lórí àwọn èso pípọ́n rẹ
àti lórí ìkórè èyí tí o ti mọ́wọ́dúró.
10Ayọ̀ àti ìdùnnú ni a ti mú kúrò
nínú ọgbà-igi eléso rẹ;
kò sí ẹnìkan tí ó kọrin tàbí
kígbe nínú ọgbà àjàrà:
ẹnikẹ́ni kò fún ọtí níbi ìfúntí,
nítorí mo ti fi òpin sí gbogbo igbe.
11Ọkàn mi kérora fún Moabu gẹ́gẹ́ bí i dùùrù,
àní tọkàntọkàn mi fún ìlú Kiri-Hareseti.
12Nígbà tí Moabu farahàn ní ibi gíga rẹ̀,
ó ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà lásán;
Nígbà tí ó lọ sí ojúbọ rẹ̀ láti gbàdúrà
òfo ni ó jásí.
13Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa Moabu. 14Ṣùgbọ́n ní àkókò yìí Olúwa wí pé: “Láàrín ọdún mẹ́ta gẹ́gẹ́ bí ìwọ̀fà tí ó wà lábẹ́ ìdè ọgbà rẹ̀ ti máa kà á, ògo Moabu àti àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn rẹ̀ ni a ó kẹ́gàn, àwọn tí ó sálà nínú rẹ̀ yóò kéré níye, wọn yóò sì jẹ́ akúrẹtẹ̀.”

Copyright information for YorBMYO